Yorùbá Bibeli

Eks 28:32-43 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Oju ọrùn yio si wà lãrin rẹ̀ fun ori; ọjá iṣẹti yio si wà yi oju rẹ̀ ká, iṣẹ-oniṣọnà gẹgẹ bi ẹ̀wu ogun, ki o má ba fàya.

33. Ati ni iṣẹti rẹ̀ nisalẹ ni iwọ o ṣe pomegranate aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, yi iṣẹti rẹ̀ ká; ati ṣaworo wurà lãrin wọn yiká;

34. Ṣaworo wurà kan ati pomegranate kan, ṣaworo wurà kan ati pomegranate kan, li eti iṣẹti aṣọ igunwa na yiká.

35. On o si wà lara Aaroni lati ma fi ṣiṣẹ: a o si ma gbọ́ iró rẹ̀ nigbati o ba wọ̀ ibi mimọ́ lọ niwaju OLUWA, ati nigbati o ba si njade bọ̀, ki o má ba kú.

36. Iwọ o si ṣe awo ni kìki wurà, iwọ o si fin sara rẹ̀, gẹgẹ bi fifin èdidi-àmi pe, MIMỌ́ SI OLUWA.

37. Iwọ o si fi i sara ọjá-àwọn alaró, ki o le ma wà lara fila nì, niwaju fila na ni ki o wà.

38. On o si ma wà niwaju ori Aaroni, ki Aaroni le ma rù ẹ̀ṣẹ ohun mimọ́, ti awọn ọmọ Israeli yio si yàsimimọ́, ninu gbogbo ẹ̀bun mimọ́ wọn: on o si ma wà niwaju ori rẹ̀ nigbagbogbo, ki OLUWA ki o le ni inudidùn si wọn.

39. Iwọ o si fi ọ̀gbọ didara wun ẹ̀wu-awọtẹlẹ, iwọ o si fi ọ̀gbọ didara ṣe fila, iwọ o si fi iṣẹ abẹ́rẹ ṣe ọjá-amure.

40. Iwọ o si dá ẹ̀wu-awọtẹlẹ fun awọn ọmọ Aaroni, iwọ o si dá ọjá-amure fun wọn, iwọ o si dá fila fun wọn, fun ogo ati fun ọṣọ́.

41. Iwọ o si fi wọn wọ̀ Aaroni arakunrin rẹ, ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀; iwọ o si ta oróro si wọn li ori, iwọ o si yà wọn simimọ́, iwọ o si sọ wọn di mimọ́, ki nwọn ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi.

42. Iwọ o si dá ṣòkoto ọ̀gbọ fun wọn lati ma fi bò ìhoho wọn, ki o ti ibadi dé itan:

43. Nwọn o si wà lara Aaroni, ati lara awọn ọmọ rẹ̀, nigbati nwọn ba wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, tabi nigbati nwọn ba sunmọ pẹpẹ, lati ṣiṣẹ ni ibi mimọ́; ki nwọn ki o má ba dẹ̀ṣẹ, nwọn a si kú: ìlana lailai ni fun u ati fun irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀.