Yorùbá Bibeli

Eks 28:1-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. IWỌ si mú Aaroni arakunrin rẹ, ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀ si ọdọ rẹ, kuro ninu awọn ọmọ Israeli, ki on ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi, ani Aaroni, Nadabu ati Abihu, Eleasari ati Itamari, awọn ọmọ Aaroni.

2. Iwọ o si dá aṣọ mimọ́ fun Aaroni arakunrin rẹ fun ogo ati fun ọṣọ́.

3. Iwọ o si sọ fun gbogbo awọn ti o ṣe amoye, awọn ẹniti mo fi ẹmi ọgbọ́n kún, ki nwọn ki o le dá aṣọ Aaroni lati yà a simimọ́, ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi.

4. Wọnyi si li aṣọ ti nwọn o dá; igbàiya kan, ati ẹ̀wu-efodi, ati aṣọ igunwà, ati ẹ̀wu-awọtẹlẹ ọlọnà, fila, ati ọjá-amure: nwọn o si dá aṣọ mimọ́ wọnyi fun Aaroni arakunrin rẹ, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, ki on ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi.

5. Nwọn o si mú wurà, ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ.

6. Nwọn o si ṣe ẹ̀wu-efodi ti wurà, ti aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ti ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ iṣẹ ọlọnà,

7. Yio ní aṣọ ejika meji ti o solù li eti rẹ̀ mejeji; bẹ̃ni ki a so o pọ̀.

8. Ati onirũru-ọnà ọjá rẹ̀, ti o wà lori rẹ̀ yio ri bakanna, gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀; ti wurà, ti aṣọ-alaró, ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ.

9. Iwọ o si mú okuta oniki meji, iwọ o si fin orukọ awọn ọmọ Israeli sara wọn:

10. Orukọ awọn mẹfa sara okuta kan, ati orukọ mẹfa iyokù sara okuta keji, gẹgẹ bi ìbí wọn.

11. Iṣẹ-ọnà afin-okuta, bi ifin èdidi-àmi, ni iwọ o fin okuta mejeji gẹgẹ bi orukọ awọn ọmọ Israeli: iwọ o si dè wọn si oju-ìde wurà.

12. Iwọ o si fi okuta mejeji si ejika ẹ̀wu-efodu na, li okuta iranti fun awọn ọmọ Israeli; Aaroni yio si ma rù orukọ wọn niwaju OLUWA li ejika rẹ̀ mejeji fun iranti.

13. Iwọ o si ṣe oju-ìde wurà:

14. Ati okùn ẹ̀wọn meji ti kìki wurà; iṣẹ ọnà-lilọ ni ki iwọ ki o fi ṣe wọn, ki iwọ ki o si so okùn ẹ̀wọn iṣẹ ọnà-lilọ ni si oju-ìde na.

15. Iwọ o si fi iṣẹ ọgbọ́n na ṣe igbàiya idajọ na; nipa iṣẹ-ọnà ẹ̀wu-efodi ni iwọ o ṣe e; ti wurà, ti aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododò, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ ni iwọ o fi ṣe e.

16. Iha mẹrin ọgbọgba ni ki iwọ ki o ṣe e ni iṣẹpo meji; ika kan ni ìna rẹ̀, ika kan si ni ibú rẹ̀.

17. Iwọ o si tò ìto okuta sinu rẹ̀, ẹsẹ̀ okuta mẹrin: ẹsẹ̀ kini, sardiu, topasi, ati smaragdu; eyi li ẹsẹ̀ kini:

18. Ẹsẹ̀ keji, emeraldi, safiru, ati diamondi;