5. Ãdọta ojóbo ni ki iwọ ki o ṣe si aṣọ-tita kan, ãdọta ojóbo ni ki iwọ ki o si ṣe si eti aṣọ-tita ti o wà ni isolù keji; ki ojóbo ki o le kọ́ ara wọn.
6. Iwọ o si ṣe ãdọta ikọ́ wurà, iwọ o si fi ikọ́ na fà awọn aṣọ-tita so: on o si jẹ́ agọ́ kan.
7. Iwọ o si ṣe aṣọ-tita irun ewurẹ, lati ṣe ibori sori agọ́ na: aṣọ-tita mọkanla ni iwọ o ṣe e.
8. Ìna aṣọ-tita kan yio jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, ati ibò aṣọ-tita kan yio jẹ́ igbọnwọ mẹrin: aṣọ-tita mọkọkanla na yio si jẹ́ ìwọn kanna.
9. Iwọ o si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn li ọ̀tọ, ati aṣọ-tita mẹfa lù mọ́ ara wọn li ọ̀tọ, iwọ o si ṣẹ aṣọ-tita kẹfa po ni meji niwaju agọ́ na.
10. Iwọ o si ṣe ãdọta ojóbo li eti aṣọ-tita na, ti o yọ si ode jù ninu isolù, ati ãdọta ojóbo li eti aṣọ-tita ti o so ekeji lù.
11. Iwọ o si ṣe ãdọta ikọ́ idẹ, ki o si fi ikọ́ wọnni sinu ojóbo, ki o si fi so agọ́ na pọ̀, yio si jẹ́ ọkan.
12. Ati iyokù ti o kù ninu aṣọ-tita agọ́ na, àbọ aṣọ-tita ti o kù, yio rọ̀ sori ẹhin agọ na.
13. Ati igbọnwọ kan li apa kan, ati igbọnwọ kan li apa keji, eyiti o kù ni ìna aṣọ-tita agọ́ na, yio si rọ̀ si ìha agọ́ na ni ìha ihin ati ni ìha ọhún, lati bò o.