Yorùbá Bibeli

Eks 25:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si sọ fun Mose pe,

2. Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, ki nwọn ki o mú ọrẹ fun mi wá: lọwọ olukuluku enia ti o ba fifunni tinutinu ni ki ẹnyin ki o gbà ọrẹ mi.

3. Eyi si li ọrẹ ti ẹnyin o gbà lọwọ wọn; wurà, ati fadakà, ati idẹ;

4. Ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ, ati irun ewurẹ;

5. Ati awọ àgbo ti a sè ni pupa, ati awọ seali, ati igi ṣittimu.

6. Oróro fun fitila, olõrùn fun oróro itasori, ati fun turari didùn;

7. Okuta oniki, ati okuta ti a o tò si ẹ̀wu-efodi, ati si igbàiya.

8. Ki nwọn ki o si ṣe ibi mimọ́ kan fun mi; ki emi ki o le ma gbé ãrin wọn.

9. Gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo fihàn ọ, nipa apẹrẹ agọ́, ati apẹrẹ gbogbo ohunèlo inu rẹ̀, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o si ṣe e.

10. Nwọn o si ṣe apoti igi ṣittimu: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni giga rẹ̀.

11. Iwọ o si fi kìki wurà bò o, ninu ati lode ni iwọ o fi bò o, iwọ o si ṣe igbáti wurà sori rẹ̀ yiká.