Yorùbá Bibeli

Eks 23:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. IWỌ kò gbọdọ gbà ìhin eke: máṣe li ọwọ́ si i pẹlu enia buburu lati ṣe ẹlẹri aiṣododo.

2. Iwọ kò gbọdọ tọ̀ ọ̀pọlọpọ enia lẹhin lati ṣe ibi, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sọ̀rọ̀ li ọ̀ran ki o tẹ̀ si ọ̀pọ enia lati yi ẹjọ́ po.

3. Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ gbè talaka li ẹjọ́ rẹ̀.

4. Bi iwọ ba bá akọmalu tabi kẹtẹkẹtẹ ọtá rẹ ti o ṣina, ki iwọ ki o mú u pada fun u wá nitõtọ.

5. Bi iwọ ba ri kẹtẹkẹtẹ ẹniti o korira rẹ, ti o dubulẹ labẹ ẹrù rẹ̀, ti iwọ iba yẹra lati bá a tú u, iwọ o bá a tú u nitõtọ.

6. Iwọ kò gbọdọ yi ẹjọ́ talaka rẹ po li ọ̀ran rẹ̀.

7. Takéte li ọ̀ran eke; ati alaiṣẹ ati olododo ni iwọ kò gbọdọ pa: nitoriti emi ki yio dá enia buburu lare.

8. Iwọ kò gbọdọ gbà ọrẹ: nitori ọrẹ ni ifọ́ awọn ti o riran loju, a si yi ọ̀ran awọn olododo po.

9. Ati pẹlu iwọ kò gbọdọ pọ́n alejò kan loju: ẹnyin sa ti mọ̀ inu alejò, nitoriti ẹnyin ti jẹ́ alejò ni ilẹ Egipti.

10. Ọdún mẹfa ni iwọ o si gbìn ilẹ rẹ, on ni iwọ o si kó eso rẹ̀ jọ.

11. Ṣugbọn li ọdún keje iwọ o jẹ ki o simi, ki o si gbé jẹ; ki awọn talaka enia rẹ ki o ma jẹ ninu rẹ̀: eyiti nwọn si fisilẹ ni ki ẹran igbẹ ki o ma jẹ. Irú bẹ̃ gẹgẹ ni iwọ o ṣe si agbalá-àjara, ati agbalá-olifi rẹ.

12. Ijọ́ mẹfa ni iwọ o ṣe iṣẹ rẹ, ni ijọ́ keje ki iwọ ki o si simi: ki akọmalu rẹ, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ ki o le simi, ki a le tù ọmọ iranṣẹbinrin rẹ, ati alejò, lara.