Yorùbá Bibeli

Eks 17:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. GBOGBO ijọ awọn ọmọ Israeli si rìn lati ijù Sini lọ, ni ìrin wọn, gẹgẹ bi ofin OLUWA, nwọn si dó ni Refidimu: omi kò si si fun awọn enia na lati mu.

2. Nitorina li awọn enia na ṣe mbá Mose sọ̀, nwọn si wipe, Fun wa li omi ki a mu. Mose si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mbà mi sọ̀? ẽṣe ti ẹnyin fi ndán OLUWA wò?

3. Ongbẹ omi si ngbẹ awọn enia na nibẹ̀; awọn enia na si nkùn si Mose, nwọn si wipe, Ẽtiri ti iwọ fi mú wa goke lati Egipti wá, lati fi ongbẹ pa wa ati awọn ọmọ wa, ati ẹran wa?

4. Mose si kepè OLUWA, wipe, Kili emi o ṣe fun awọn enia yi? nwọn fẹrẹ̀ sọ mi li okuta.