Yorùbá Bibeli

Eks 11:4-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Mose si wipe, Bayi li OLUWA wi, Lãrin ọganjọ li emi o jade lọ sãrin Egipti:

5. Gbogbo awọn akọ́bi ti o wà ni ilẹ Egipti ni yio si kú, lati akọ́bi Farao lọ ti o joko lori itẹ́ rẹ̀, titi yio si fi dé akọ́bi iranṣẹbinrin ti o wà lẹhin ọlọ; ati gbogbo akọ́bi ẹran.

6. Ẹkún nla yio si wà ni gbogbo ilẹ Egipti, eyiti irú rẹ̀ kò si ri, ti ki yio si si irú rẹ̀ mọ́.

7. Ṣugbọn si ọkan ninu awọn ọmọ Israeli li ajá ki yio yọ ahọn rẹ̀, si enia tabi si ẹran: ki ẹnyin ki o le mọ̀ bi OLUWA ti fi ìyatọ sãrin awọn ara Egipti ati Israeli.

8. Gbogbo awọn iranṣẹ rẹ wọnyi ni yio si sọkalẹ tọ̀ mi wá, ti nwọn o si fori wọn balẹ fun mi pe, Iwọ jade lọ ati gbogbo awọn enia ẹhin rẹ: lẹhin ìgba na li emi o to jade. O si jade kuro niwaju Farao ni ibinu nla.

9. OLUWA si wi fun Mose pe, Farao ki yio gbọ́ tirẹ; ki a le sọ iṣẹ-iyanu mi di pupọ̀ ni ilẹ Egipti.

10. Mose ati Aaroni si ṣe gbogbo iṣẹ-iyanu wọnyi niwaju Farao: OLUWA si mu àiya Farao le, bẹ̃ni kò si fẹ́ jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o jade lọ kuro ni ilẹ rẹ̀.