Yorùbá Bibeli

Amo 9:5-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun li ẹniti o si fi ọwọ́ kan ilẹ na, yio si di yiyọ́, gbogbo awọn ti o ngbe inu rẹ̀ yio si ṣọ̀fọ: yio si rú soke patapata bi kikun omi: a o si tẹ̀ ẹ ri, bi odò Egipti.

6. On li ẹniti o kọ́ itẹ́ rẹ̀ ninu awọn ọrun, ti o si fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ ni ilẹ aiye: ẹniti o pè awọn omi okun, ti o si tú wọn jade si ori ilẹ aiye: Oluwa li orukọ rẹ̀.

7. Ẹnyin kò ha dàbi awọn ọmọ Etiopia si mi, Ẹnyin ọmọ Israeli? li Oluwa wi. Emi kò ha ti mu Israeli goke ti ilẹ Egipti jade wá? ati awọn Filistini lati ilẹ Kaftori, ati awọn ara Siria lati Kiri.

8. Kiyesi i, Oluwa Ọlọrun mbẹ lara ilẹ ọba ti o kún fun ẹ̀ṣẹ, emi o si pa a run kuro lori ilẹ; ṣugbọn emi kì yio pa ile Jakobu run tan patapata, li Oluwa wi.

9. Wò o, nitori emi o paṣẹ, emi o si kù ile Israeli ninu awọn orilẹ-ède, bi ã ti kù ọkà ninu kọ̀nkọsọ, ṣugbọn woro kikini kì yio bọ́ sori ilẹ.

10. Gbogbo awọn ẹlẹṣẹ ninu enia mi yio ti ipa idà kú, ti nwipe, Ibi na kì yio le wa ba, bẹ̃ni kì yio ba wa lojijì.