Yorùbá Bibeli

A. Oni 1:1-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe lẹhin ikú Joṣua, ni awọn ọmọ Israeli bère lọdọ OLUWA wipe, Tani yio tète gòke tọ̀ awọn ara Kenaani lọ fun wa, lati bá wọn jà?

2. OLUWA si wipe, Juda ni yio gòke lọ: kiyesi i, emi fi ilẹ̀ na lé e lọwọ.

3. Juda si wi fun Simeoni arakunrin rẹ̀ pe, Bá mi gòke lọ si ilẹ mi, ki awa ki o le bá awọn ara Kenaani jà; emi na pẹlu yio si bá ọ lọ si ilẹ rẹ. Simeoni si bá a lọ.

4. Juda si gòke lọ; OLUWA si fi awọn ara Kenaani ati awọn Perissi lé wọn lọwọ: nwọn si pa ẹgbarun ọkunrin ninu wọn ni Beseki.

5. Nwọn si ri Adoni-beseki ni Beseki: nwọn si bá a jà, nwọn si pa awọn ara Kenaani ati awọn Perissi.

6. Ṣugbọn Adoni-beseki sá; nwọn si lepa rẹ̀, nwọn si mú u, nwọn si ke àtampako ọwọ́ rẹ̀, ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀.

7. Adoni-beseki si wipe, Adọrin ọba li emi ke li àtampako ọwọ́ wọn ati ti ẹsẹ̀ wọn, ti nwọn nṣà onjẹ wọn labẹ tabili mi: gẹgẹ bi emi ti ṣe, bẹ̃li Ọlọrun si san a fun mi. Nwọn si mú u wá si Jerusalemu, o si kú sibẹ̀.

8. Awọn ọmọ Juda si bá Jerusalemu jà, nwọn si kó o, nwọn si fi oju idà kọlù u, nwọn si tinabọ ilu na.

9. Lẹhin na awọn ọmọ Juda si sọkalẹ lọ lati bá awọn ara Kenaani jà, ti ngbé ilẹ òke, ati ni Gusù, ati ni afonifoji nì.

10. Juda si tọ̀ awọn ara Kenaani ti ngbé Hebroni lọ: (orukọ Hebroni ni ìgba iṣaju si ni Kiriati-arba:) nwọn si pa Ṣeṣai, ati Ahimani, ati Talmai.

11. Lati ibẹ̀ o si gbé ogun tọ̀ awọn ara Debiri lọ. (Orukọ Debiri ni ìgba atijọ si ni Kiriati-seferi.)

12. Kalebu si wipe, Ẹniti o ba kọlù Kiriati-seferi, ti o si kó o, on li emi o fi Aksa ọmọbinrin mi fun li aya.

13. Otnieli ọmọ Kenasi, aburò Kalebu, si kó o: o si fi Aksa ọmọbinrin rẹ̀ fun u li aya.

14. O si ṣe, nigbati Aksa dé ọdọ rẹ̀, o si rọ̀ ọ lati bère oko kan lọdọ baba rẹ̀: Aksa si sọkalẹ kuro lori kẹtẹkẹtẹ rẹ̀; Kalebu si wi fun u pe, Kini iwọ nfẹ́?

15. On si wi fun u pe, Ta mi lọrẹ kan; nitoriti iwọ ti fun mi ni ilẹ Gusù, fi isun omi fun mi pẹlu. Kalebu si fi ìsun òke ati isun isalẹ fun u.