9. Sa wò o, awọn ọta rẹ, Oluwa, sa wò o, awọn ọta rẹ yio ṣegbe; gbogbo oniṣẹ ẹ̀ṣẹ li a o tuka.
10. Ṣugbọn iwo mi ni iwọ o gbé ga bi iwo agbanrere; ororo titun li a o ta si mi lori.
11. Oju mi pẹlu yio ri ifẹ mi lara awọn ọta mi, eti mi yio si ma gbọ́ ifẹ mi si awọn enia buburu ti o dide si mi.
12. Olododo yio gbà bi igi ọpẹ: yio dàgba bi igi kedari Lebanoni.