Yorùbá Bibeli

O. Daf 84 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ṣíṣàárò Ilé Ọlọrun

1. AGỌ rẹ wọnni ti li ẹwà to, Oluwa awọn ọmọ-ogun!

2. Ọkàn mi nfà nitõtọ, o tilẹ pe ongbẹ fun agbala Oluwa: aiya mi ati ara mi nkigbe si Ọlọrun alãye.

3. Nitõtọ, ologoṣẹ ri ile, ati alapandẹdẹ tẹ́ itẹ fun ara rẹ̀, nibiti yio gbe ma pa awọn ọmọ rẹ̀ mọ́ si, ani ni pẹpẹ rẹ wọnni, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọba mi ati Ọlọrun mi.

4. Ibukún ni fun awọn ti ngbe inu ile rẹ: nwọn o ma yìn ọ sibẹ.

5. Ibukún ni fun enia na, ipá ẹniti o wà ninu rẹ: li ọkàn ẹniti ọ̀na rẹ wà.

6. Awọn ti nla afonifoji omije lọ, nwọn sọ ọ di kanga; akọrọ-òjo si fi ibukún bò o.

7. Nwọn nlọ lati ipá de ipá, ni Sioni ni awọn yọ niwaju Ọlọrun.

8. Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, gbọ́ adura mi; fi eti si i, Ọlọrun Jakobu.

9. Kiyesi i, Ọlọrun asà wa, ki o si ṣiju wò oju Ẹni-ororo rẹ.

10. Nitori pe ọjọ kan ninu agbala rẹ sanju ẹgbẹrun ọjọ lọ. Mo fẹ ki nkuku ma ṣe adena ni ile Ọlọrun mi, jù lati ma gbe agọ ìwa-buburu.

11. Nitori Oluwa Ọlọrun li õrun ati asà: Oluwa yio fun ni li ore-ọfẹ ati ogo: kò si ohun rere ti yio fà sẹhin lọwọ awọn ti nrìn dede.

12. Oluwa awọn ọmọ-ogun, ibukún ni fun oluwarẹ̀ na ti o gbẹkẹle ọ.