Yorùbá Bibeli

O. Daf 62 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ọlọrun ni Ààbò Wa

1. ỌLỌRUN nikan li ọkàn mi duro jẹ dè; lati ọdọ rẹ̀ wá ni igbala mi.

2. On nikan li apata mi ati igbala mi; on li àbo mi, emi kì yio ṣipò pada jọjọ.

3. Ẹnyin o ti ma rọlu enia kan pẹ to? gbogbo nyin li o fẹ pa a: bi ogiri ti o bìwó ati bi ọgbà ti nwó lọ.

4. Kiki ìro wọn ni lati já a tilẹ kuro ninu ọlá rẹ̀: nwọn nṣe inu didùn ninu eke: nwọn nfi ẹnu wọn sure, ṣugbọn nwọn ngegun ni inu wọn.

5. Ọkàn mi, iwọ sa duro jẹ de Ọlọrun; nitori lati ọdọ rẹ̀ wá ni ireti mi.

6. On nikan li apata mi ati igbala mi: on li àbo mi; a kì yio ṣi mi ni ipò.

7. Nipa Ọlọrun ni igbala mi, ati ogo mi: apata agbara mi, àbo mi si mbẹ ninu Ọlọrun.

8. Gbẹkẹle e nigbagbogbo; ẹnyin enia, tú ọkàn nyin jade niwaju rẹ̀; Ọlọrun àbo fun wa.

9. Nitõtọ asan li awọn ọmọ enia, eke si li awọn oloyè. Nwọn gòke ninu ìwọn, bakanna ni nwọn fẹrẹ jù asan lọ.

10. Máṣe gbẹkẹle inilara, ki o má si ṣe gberaga li olè jija: bi ọrọ̀ ba npọ̀ si i, máṣe gbe ọkàn nyin le e.

11. Ọlọrun ti sọ̀rọ lẹ̃kan; lẹ̃rinkeji ni mo gbọ́ eyi pe: ti Ọlọrun li agbara.

12. Pẹlupẹlu, Oluwa, tirẹ li ãnu: nitoriti iwọ san a fun olukulùku enia gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀.