Yorùbá Bibeli

O. Daf 5 Yorùbá Bibeli (YCE)

Adura Ààbò

1. FI eti si ọ̀rọ mi, Oluwa, kiyesi aroye mi.

2. Fi eti si ohùn ẹkún mi, Ọba mi, ati Ọlọrun mi: nitoripe ọdọ rẹ li emi o ma gbadura si.

3. Ohùn mi ni iwọ o gbọ́ li owurọ, Oluwa, li owurọ li emi o gbà adura mi si ọ, emi o si ma wòke.

4. Nitori ti iwọ kì iṣe Ọlọrun ti iṣe inu-didùn si ìwa buburu: bẹ̃ni ibi kò le ba ọ gbe.

5. Awọn agberaga kì yio le duro niwaju rẹ: iwọ korira gbogbo awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.

6. Iwọ o pa awọn ti nṣe eke run; Oluwa yio korira awọn ẹni-ẹ̀jẹ ati ẹni-ẹ̀tan.

7. Ṣugbọn bi o ṣe ti emi, emi o wá sinu ile rẹ li ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ: ninu ẹ̀ru rẹ li emi o tẹriba si iha tempili mimọ́ rẹ.

8. Tọ́ mi, Oluwa, ninu ododo rẹ, nitori awọn ọta mi: mu ọ̀na rẹ tọ́ tàra niwaju mi.

9. Nitori ti otitọ kan kò si li ẹnu ẹnikẹni wọn; ikakika ni iha inu wọn; isa-okú ti o ṣi silẹ li ọfun wọn; ahọn wọn ni nwọn fi npọ́nni.

10. Iwọ da wọn lẹbi, Ọlọrun; ki nwọn ki o ti ipa ìmọ ara wọn ṣubu; já wọn kuro nitori ọ̀pọlọpọ irekọja wọn; nitori ti nwọn ti ṣọ̀tẹ si ọ.

11. Nigbana ni gbogbo awọn ti ngbẹkẹle ọ yio yọ̀; lai nwọn o ma ho fun ayọ̀, nitoriti iwọ dabobo wọn: ati awọn ti o fẹ orukọ rẹ pẹlu yio ma yọ̀ ninu rẹ.

12. Nitori iwọ, Oluwa, ni yio bukún fun olododo; oju-rere ni iwọ o fi yi i ka bi asà.