9. Oluwa ṣeun fun ẹni gbogbo; iyọ́nu rẹ̀ si mbẹ lori iṣẹ rẹ̀ gbogbo.
10. Oluwa, gbogbo iṣẹ rẹ ni yio ma yìn ọ; awọn enia mimọ́ rẹ yio si ma fi ibukún fun ọ.
11. Nwọn o ma sọ̀rọ ogo ijọba rẹ, nwọn o si ma sọ̀rọ agbara rẹ:
12. Lati mu iṣẹ agbara rẹ̀ di mimọ̀ fun awọn ọmọ enia, ati ọla-nla ijọba rẹ̀ ti o logo,
13. Ijọba rẹ ijọba aiye-raiye ni, ati ijọba rẹ lati iran-diran gbogbo.
14. Oluwa mu gbogbo awọn ti o ṣubu ró; o si gbé gbogbo awọn ti o tẹriba dide.