Yorùbá Bibeli

O. Daf 118 Yorùbá Bibeli (YCE)

Adura Ọpẹ́ fún Ìṣẹ́gun

1. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa; nitoriti o ṣeun, nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai.

2. Jẹ ki Israeli ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai.

3. Jẹ ki ara-ile Aaroni ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai.

4. Jẹ ki awọn ti o bẹ̀ru Oluwa ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai.

5. Mo kepè Oluwa ninu ipọnju: Oluwa si da mi lohùn ni ibi àye nla.

6. Oluwa mbẹ fun mi, emi kì yio bẹ̀ru; kili enia le ṣe si mi?

7. Oluwa mbẹ fun mi pẹlu awọn ti nràn mi lọwọ: nitorina li emi o ṣe ri ifẹ mi lori awọn ti o korira mi.

8. O ya lati gbẹkẹle Oluwa, jù ati gbẹkẹle enia lọ.

9. O ya lati gbẹkẹle Oluwa, jù ati gbẹkẹle awọn ọmọ-alade lọ.

10. Gbogbo awọn orilẹ-ède yi mi ka kiri, ṣugbọn li orukọ Oluwa emi o pa wọn run.

11. Nwọn yi mi ka kiri; nitõtọ, nwọn yi mi ka kiri, ṣugbọn li orukọ Oluwa emi o pa wọn run.

12. Nwọn yi mi ka kiri bi oyin; a si pa wọn bi iná ẹgún: li orukọ Oluwa emi o sa pa wọn run.

13. Iwọ tì mi gidigidi ki emi ki o le ṣubu; ṣugbọn Oluwa ràn mi lọwọ.

14. Oluwa li agbara ati orin mi, o si di igbala mi.

15. Ìró ayọ̀ ati ti ìṣẹ́gun mbẹ ninu agọ awọn olododo; ọwọ ọtún Oluwa li a gbega: ọwọ ọtún Oluwa nṣe agbara.

16. Ọwọ ọtún Oluwa li a gbega: ọwọ ọtún Oluwa nṣe agbara.

17. Emi kì yio kú, bikoṣe yiyè, ki emi ki o si ma rohin iṣẹ Oluwa.

18. Oluwa nà mi gidigidi: ṣugbọn kò fi mi fun ikú.

19. Ṣi ilẹkun ẹnu-ọ̀na ododo silẹ fun mi: emi o ba ibẹ wọle, emi o ma yìn Oluwa.

20. Eyi li ẹnu-ọ̀na Oluwa, ti awọn olododo yio ba wọle.

21. Emi o yìn ọ: nitori ti iwọ gbohùn mi, iwọ si di igbala mi.

22. Okuta ti awọn ọ̀mọle kọ̀ silẹ li o di pataki igun ile.

23. Lati ọdọ Oluwa li eyi: o ṣe iyanu li oju wa.

24. Eyi li ọjọ ti Oluwa da: awa o ma yọ̀, inu wa yio si ma dùn ninu rẹ̀.

25. Ṣe igbala nisisiyi, emi mbẹ ọ, Oluwa: Oluwa emi bẹ ọ, rán alafia.

26. Olubukún li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa: awa ti fi ibukún fun ọ lati ile Oluwa wá.

27. Ọlọrun li Oluwa, ti o ti fi imọlẹ hàn fun wa: ẹ fi okùn di ẹbọ na mọ́ iwo pẹpẹ na.

28. Iwọ li Ọlọrun mi, emi o si ma yìn ọ, iwọ li Ọlọrun mi, emi o mã gbé ọ ga.

29. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa; nitori ti o ṣeun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.