JOṢUA si pè gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli jọ si Ṣekemu, o si pè awọn àgba Israeli, ati awọn olori wọn, ati awọn onidajọ wọn, ati awọn ijoye wọn; nwọn si fara wọn hàn niwaju Ọlọrun.