1. O SI fi igi ṣittimu ṣe pẹpẹ ẹbọsisun: igbọnwọ marun ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ marun ni ibú rẹ̀; onìha mẹrin ọgbọgba ni; igbọnwọ mẹta si ni giga rẹ̀.
2. O si ṣe iwo rẹ̀ si i ni igun rẹ̀ mẹrẹrin; iwo rẹ̀ wà lara rẹ̀: o si fi idẹ bò o.
3. O si ṣe gbogbo ohunèlo pẹpẹ na, ìkoko rẹ̀, ọkọ́ rẹ̀, ati awokòto rẹ̀, ati kọkọrọ ẹran rẹ̀, ati awo iná wọnni: gbogbo ohunèlo rẹ̀ li o fi idẹ ṣe.
4. O si ṣe àro idẹ fun pẹpẹ na ni iṣẹ àwọn nisalẹ ayiká rẹ̀, dé agbedemeji rẹ̀.
5. O si dà oruka mẹrin fun ìku mẹrẹrin àro idẹ na, li àye fun ọpá wọnni.
6. O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, o si fi idẹ bò wọn.
7. O si fi ọpá wọnni sinu oruka ni ìha pẹpẹ na, lati ma fi rù u; o fi apáko ṣe pẹpẹ na li onihò ninu.
8. O si fi idẹ ṣe agbada na, o si fi idẹ ṣe ẹsẹ̀ rẹ̀, ti awojiji ẹgbẹ awọn obinrin ti npejọ lati sìn li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
9. O si ṣe agbalá na: ni ìha gusù li ọwọ́ ọtún aṣọ-tita agbalá na jẹ́ ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ọgọrun igbọnwọ:
10. Opó wọn jẹ́ ogún, ihò-ìtẹbọ idẹ wọn jẹ́ ogún; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà.
11. Ati fun ìha ariwa ọgọrun igbọnwọ, opó wọn jẹ́ ogún, ati ihò-ìtẹbọ idẹ wọn jẹ́ ogún; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà.
12. Ati fun ìha ìwọ-õrùn li aṣọ-tita ãdọta igbọnwọ, opó wọn mẹwa, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹwa; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà.
13. Ati fun ìha ìla-õrùn, si ìha ìla-õrùn ãdọta igbọnwọ.
14. Aṣọ-tita apakan jẹ́ igbọnwọ mẹdogun; opó wọn jẹ́ mẹta, ati ihò-ìtẹbọ wọn jẹ́ mẹta.