Yorùbá Bibeli

Tit 1:10-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Nitoripe ọpọlọpọ awọn alagídi, awọn asọ̀rọ asan, ati awọn ẹlẹtàn ni mbẹ, papa awọn ti ikọla:

11. Awọn ẹniti a kò le ṣaipa li ẹnu mọ, nitoriti wọn nda odidi agbo ilé rú, ti nwọn nkọni ni ohun ti kò yẹ nitori ere aitọ́.

12. Ọkan ninu wọn, ani woli awọn tikarawọn, wipe, Eke ni awọn ará Krete nigbagbogbo, ẹranko buburu, ọlẹ alajẹki.

13. Otitọ li ẹrí yi. Nitorina bá wọn wi gidigidi, ki nwọn ki o le yè kõro ni igbagbọ́;

14. Ki nwọn máṣe fiyesi ìtan lasan ti awọn Ju, ati ofin awọn enia ti nwọn yipada kuro ninu otitọ.

15. Ohun gbogbo ni o mọ́ fun awọn ẹniti o mọ́, ṣugbọn fun awọn ti a sọ di ẹlẹgbin ati awọn alaigbagbọ́ kò si ohun ti o mọ́; ṣugbọn ati inu ati ẹ̀ri-ọkan wọn li a sọ di ẹgbin.

16. Nwọn jẹwọ pe nwọn mọ̀ Ọlọrun; ṣugbọn nipa iṣẹ nwọn nsẹ́ ẹ, nwọn jẹ ẹni irira, ati alaigbọran, ati niti iṣẹ rere gbogbo alainilari.