Yorùbá Bibeli

Tit 1:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. PAULU, iranṣẹ Ọlọrun, ati Aposteli Jesu Kristi, gẹgẹ bi igbagbọ́ awọn ayanfẹ Ọlọrun, ati imọ otitọ ti mbẹ gẹgẹ bi ìwa-bi-Ọlọrun,

2. Ni ireti ìye ainipẹkun, ti Ọlọrun, Ẹniti kò le ṣèké, ti ṣe ileri ṣaju ipilẹṣẹ aiye;

3. Ṣugbọn ni akokò tirẹ̀ o fi ọ̀rọ rẹ̀ hàn ninu iwasu, ti a fi le mi lọwọ gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun Olugbala wa;

4. Si Titu, ọmọ mi nitõtọ nipa igbagbọ́ ti iṣe ti gbogbo enia: Ore-ọfẹ, ãnu, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wá ati Kristi Jesu Olugbala wa.

5. Nitori idi eyi ni mo ṣe fi ọ silẹ ni Krete, ki iwọ ki o le ṣe eto ohun ti o kù, ki o si yan awọn alagba ni olukuluku ilu, bi mo ti paṣẹ fun ọ.

6. Bi ẹnikan ba ṣe alailẹgan, ọkọ aya kan, ti o ni ọmọ ti o gbagbọ́, ti a kò fi sùn fun wọbia, ti nwọn kò si jẹ alagidi.

7. Nitori o yẹ ki biṣopu jẹ alailẹgàn, bi iriju Ọlọrun; ki o má jẹ aṣe-tinu-ẹni, oninu-fùfu, ọmuti, aluni, olojukokoro;

8. Bikoṣe olufẹ alejò ṣiṣe, olufẹ awọn enia rere, alairekọja, olõtọ, ẹni mimọ́, ẹni iwọntunwọnsi;

9. Ti o ndì ọ̀rọ otitọ mu ṣinṣin eyiti iṣe gẹgẹ bi ẹ̀kọ́, ki on ki o le mã gbani-niyanju ninu ẹ̀kọ́ ti o yè kõro, ki o si le mã da awọn asọrọ-odi lẹbi.

10. Nitoripe ọpọlọpọ awọn alagídi, awọn asọ̀rọ asan, ati awọn ẹlẹtàn ni mbẹ, papa awọn ti ikọla: