Yorùbá Bibeli

Rut 2:21-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Rutu obinrin Moabu na si wipe, O wi fun mi pẹlu pe, Ki iwọ ki o faramọ́ awọn ọdọmọkunrin mi, titi nwọn o fi pari gbogbo ikore mi.

22. Naomi si wi fun Rutu aya-ọmọ rẹ̀ pe, O dara, ọmọbinrin mi, ki iwọ ki o ma bá awọn ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ jade, ki nwọn ki o má ṣe bá ọ pade li oko miran.

23. Bẹ̃li o faramọ́ awọn ọmọbinrin ọdọ Boasi lati ma peṣẹ́-ọkà titi ipari ikore ọkà-barle ati ti alikama; o si wà lọdọ iya-ọkọ rẹ̀.