Yorùbá Bibeli

Rom 3:24-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Awọn ẹniti a ndalare lọfẹ nipa ore-ọfẹ rẹ̀, nipa idande ti o wà ninu Kristi Jesu:

25. Ẹniti Ọlọrun ti gbe kalẹ lati jẹ ètutu nipa igbagbọ́ ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, lati fi ododo rẹ̀ hàn nitori idariji awọn ẹ̀ṣẹ ti o ti kọja, ninu ipamọra Ọlọrun;

26. Lati fi ododo rẹ̀ hàn ni igba isisiyi: ki o le jẹ olódodo ati oludare ẹniti o gbà Jesu gbọ́.

27. Ọna iṣogo da? A ti mu u kuro. Nipa ofin wo? ti iṣẹ? Bẹ́kọ: ṣugbọn nipa ofin igbagbọ́.

28. Nitorina a pari rẹ̀ si pe nipa igbagbọ́ li a nda enia lare laisi iṣẹ ofin.

29. Ọlọrun awọn Ju nikan ha ni bi? ki ha ṣe ti awọn Keferi pẹlu? Bẹ̃ni, ti awọn Keferi ni pẹlu:

30. Bi o ti jẹ pe Ọlọrun kan ni, ti yio da awọn akọla lare nipa igbagbọ́, ati awọn alaikọla nitori igbagbọ́ wọn.

31. Awa ha nsọ ofin dasan nipa igbagbọ́ bi? Ki a má ri: ṣugbọn a nfi ofin mulẹ.