1. NJẸ anfani ki ha ni ti Ju? tabi kini ère ilà kíkọ?
2. Pipọ lọna gbogbo; ekini, nitoripe awọn li a fi ọ̀rọ Ọlọrun le lọwọ.
3. Njẹ ki ha ni bi awọn kan jẹ alaigbagbọ́? aigbagbọ́ wọn yio ha sọ otitọ Ọlọrun di asan bi?
4. Ki a má ri: k'Ọlọrun jẹ olõtọ, ati olukuluku enia jẹ eke; gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ki a le da ọ lare ninu ọ̀rọ rẹ, ṣugbọn ki iwọ le ṣẹgun nigbati iwọ ba wá si idajọ.
5. Ṣugbọn bi aiṣododo wa ba nyìn ododo Ọlọrun, kili awa o wi? Ọlọrun ti nfi ibinu rẹ̀ han ha ṣe alaiṣododo bi? (Mo fi ṣe akawe bi enia.)
6. Ki a má ri: bi bẹ̃ni, Ọlọrun yio ha ṣe le dajọ araiye?
7. Nitori bi otitọ Ọlọrun ba di pipọ si iyìn rẹ̀ nitori eke mi, ẽṣe ti a fi nda mi lẹjọ bi ẹlẹṣẹ mọ́ si?