Yorùbá Bibeli

Rom 2:20-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Olukọ awọn alaimoye, olukọ awọn ọmọde, ẹniti o ni afarawe imọ ati otitọ ofin li ọwọ.

21. Njẹ iwọ ti o nkọ́ ẹlomiran, iwọ kò kọ́ ara rẹ? iwọ ti o nwasu ki enia ki o má jale, iwọ njale?

22. Iwọ ti o nwipe ki enia ki o máṣe panṣaga, iwọ nṣe panṣaga? iwọ ti o ṣe họ̃ si oriṣa, iwọ njà tẹmpili li ole?

23. Iwọ ti nṣogo ninu ofin, ni riru ofin iwọ bù Ọlọrun li ọlá kù?

24. Nitori orukọ Ọlọrun sá di isọrọ-buburu si ninu awọn Keferi nitori nyin, gẹgẹ bi a ti kọ ọ.

25. Nitori ikọla li ère lõtọ, bi iwọ ba pa ofin mọ́: ṣugbọn bi iwọ ba jẹ arufin, ikọla rẹ di aikọla.

26. Nitorina bi alaikọla ba pa ilana ofin mọ́, a kì yio ha kà aikọla rẹ̀ si ikọla bi?

27. Alaikọla nipa ti ẹda, bi o ba pa ofin mọ́, kì yio ha da ẹbi fun iwọ ti o jẹ arufin nipa ti iwe ati ikọla?

28. Kì iṣe eyi ti o farahan ni Ju, bẹni kì iṣe eyi ti o farahan li ara ni ikọla:

29. Ṣugbọn Ju ti inu ni Ju, ati ikọla ti ọkàn, ninu ẹmi ni, kì iṣe ti ode ara; iyìn ẹniti kò si lọdọ enia, bikoṣe lọdọ Ọlọrun.