Yorùbá Bibeli

Rom 16:11-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Ẹ kí Herodioni, ibatan mi. Ẹ kí awọn arãle Narkissu, ti o wà ninu Oluwa.

12. Ẹ kí Trifena ati Trifosa, awọn ẹniti nṣe lãlã ninu Oluwa. Ẹ kí Persi olufẹ, ti o nṣe lãlã pipọ ninu Oluwa.

13. Ẹ kí Rufu ti a yàn ninu Oluwa, ati iya rẹ̀ ati ti emi.

14. Ẹ kí Asinkritu, Flegoni, Herma, Patroba, Herme, ati awọn arakunrin ti o wà pẹlu wọn.

15. Ẹ kí Filologu, ati Julia, Nereu, ati arabinrin rẹ̀, ati Olimpa, ati gbogbo awọn enia mimọ́ ti o wà pẹlu wọn.

16. Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ ki ara nyin. Gbogbo ijọ Kristi kí nyin.

17. Ará, emi si bẹ̀ nyin, ẹ mã ṣọ awọn ti nṣe ìyapa, ati awọn ti nmu ohun ikọsẹ̀ wá lodi si ẹkọ́ ti ẹnyin kọ́; ẹ si kuro ni isọ wọn.

18. Nitori awọn ti o ri bẹ̃ kò sìn Jesu Kristi Oluwa wa, bikoṣe ikùn ara wọn; ọ̀rọ rere ati ọ̀rọ didùndidùn ni nwọn fi npa awọn ti kò mọ̀ meji li ọkàn dà.

19. Nitori igbagbọ́ nyin tàn kalẹ de ìbi gbogbo. Nitorina mo ni ayọ̀ lori nyin: ṣugbọn emi fẹ ki ẹ jẹ ọlọgbọn si ohun ti o ṣe rere, ki ẹ si ṣe òpe si ohun ti iṣe buburu.

20. Ọlọrun alafia yio si tẹ̀ Satani mọlẹ li atẹlẹsẹ nyin ni lọ̃lọ. Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa ki o wà pẹlu nyin. Amin.

21. Timotiu, alabaṣiṣẹ mi, ati Lukiu, ati Jasoni, ati Sosipateru, awọn ibatan mi, ki nyin.