Yorùbá Bibeli

Rom 16:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. MO fi Febe, arabinrin wa, le nyin lọwọ ẹniti iṣe diakoni ijọ ti o wà ni Kenkrea:

2. Ki ẹnyin le gbà a ninu Oluwa, bi o ti yẹ fun awọn enia mimọ́, ki ẹnyin ki o si ràn a lọwọ iṣẹkiṣẹ ti o nwá ni iranlọwọ lọdọ nyin: nitori on pẹlu ti nṣe oluranlọwọ fun ẹni pipọ, ati fun emi na pẹlu.

3. Ẹ kí Priskilla ati Akuila, awọn alabaṣiṣẹ mi ninu Kristi Jesu:

4. Awọn ẹniti, nitori ẹmí mi, nwọn fi ọrùn wọn lelẹ: fun awọn ẹniti kì iṣe kiki emi nikan li o ndupẹ, ṣugbọn gbogbo ijọ larin awọn Keferi pẹlu.

5. Ẹ si kí ijọ ti o wà ni ile wọn. Ẹ ki Epenetu, olufẹ mi ọwọn, ẹniti iṣe akọso Asia fun Kristi.

6. Ẹ kí Maria, ti o ṣe lãla pipọ lori wa.

7. Ẹ kí Androniku ati Junia, awọn ibatan mi, ati awọn ẹgbẹ mi ninu tubu, awọn ẹniti o ni iyìn lọdọ awọn Aposteli, awọn ẹniti o ti wà ninu Kristi ṣaju mi pẹlu.

8. Ẹ kí Ampliatu olufẹ mi ninu Oluwa.

9. Ẹ kí Urbani, alabaṣiṣẹ wa ninu Kristi, ati Staki olufẹ mi.