Yorùbá Bibeli

Rom 13:8-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ẹ máṣe jẹ ẹnikẹni ni gbese ohun kan, bikoṣepe ki a fẹran ọmọnikeji ẹni: nitori ẹniti o ba fẹran ọmọnikeji rẹ̀, o kó ofin já.

9. Nitori eyi, Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga, Iwọ kò gbọdọ pania, Iwọ kò gbọdọ jale, Iwọ kò gbọdọ jẹri eke, Iwọ kò gbọdọ ṣojukòkoro; bi ofin miran ba si wà, a ko o pọ ninu ọ̀rọ yi pe, Fẹran ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ.

10. Ifẹ kì iṣe ohun buburu si ọmọnikeji rẹ̀: nitorina ifẹ li akója ofin.

11. Ati eyi, bi ẹ ti mọ̀ akokò pe, o ti to wakati nisisiyi fun nyin lati ji loju orun: nitori nisisiyi ni igbala wa sunmọ etile jù igbati awa ti gbagbọ́ lọ.

12. Oru bukọja tan, ilẹ si fẹrẹ mọ́: nitorina ẹ jẹ ki a bọ́ ara iṣẹ òkunkun silẹ, ki a si gbe ihamọra imọlẹ wọ̀.

13. Jẹ ki a mã rìn ìrin titọ, bi li ọsán; kì iṣe ni iréde-oru ati ni imutipara, kì iṣe ni iwa-ẽri ati wọbia, kì iṣe ni ìja ati ilara.

14. Ṣugbọn ẹ gbe Jesu Kristi Oluwa wọ̀, ki ẹ má si pèse fun ara, lati mã mu ifẹkufẹ rẹ̀ ṣẹ.