Yorùbá Bibeli

Rom 11:5-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Gẹgẹ bẹ̃ si ni li akokò isisiyi pẹlu, apakan wà nipa iyanfẹ ti ore-ọfẹ.

6. Bi o ba si ṣepe nipa ti ore-ọfẹ ni, njẹ kì iṣe ti iṣẹ mọ́: bi bẹ̃ kọ́, ore-ọfẹ kì iṣe ore-ọfẹ mọ́. Ṣugbọn biobaṣepe nipa ti iṣẹ́ ni, njẹ kì iṣe ti ore-ọfẹ mọ́: bi bẹ̃ kọ́, iṣẹ kì iṣe iṣẹ mọ́.

7. Ki ha ni? ohun ti Israeli nwá kiri, on na ni kò ri; ṣugbọn awọn ẹni iyanfẹ ti ri i, a si sé aiya awọn iyokù le:

8. Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ọlọrun ti fun wọn li ẹmí orun: oju ki nwọn ki o má le woran, ati etí ki nwọn ki o má le gbọran, titi o fi di oni-oloni.

9. Dafidi si wipe, Jẹ ki tabili wọn ki o di idẹkun, ati ẹgẹ́, ati ohun ikọsẹ, ati ẹsan fun wọn:

10. Ki oju wọn ki o ṣokun, ki nwọn ki o má le riran, ki o si tẹ̀ ẹhin wọn ba nigbagbogbo.