Yorùbá Bibeli

Rom 11:29-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

29. Nitori ailábámọ̀ li ẹ̀bun ati ipe Ọlọrun.

30. Nitori gẹgẹ bi ẹnyin kò ti gbà Ọlọrun gbọ́ ri, ṣugbọn nisisiyi ti ẹnyin ri ãnu gbà nipa aigbagbọ́ wọn:

31. Gẹgẹ bẹ̃li awọn wọnyi ti o ṣe aigbọran nisisiyi, ki awọn pẹlu ba le ri ãnu gbà nipa ãnu ti a fi hàn nyin.

32. Nitori Ọlọrun sé gbogbo wọn mọ pọ̀ sinu aigbagbọ́, ki o le ṣãnu fun gbogbo wọn.

33. Ã! ijinlẹ ọrọ̀ ati ọgbọ́n ati ìmọ Ọlọrun! awamáridi idajọ rẹ̀ ti ri, ọ̀na rẹ̀ si jù awari lọ!

34. Nitori tali o mọ̀ inu Oluwa? tabi tani iṣe ìgbimọ rẹ̀?

35. Tabi tali o kọ́ fifun u, ti a o si san a pada fun u?

36. Nitori lati ọdọ rẹ̀, ati nipa rẹ̀, ati fun u li ohun gbogbo: ẹniti ogo wà fun lailai. Amin.