Yorùbá Bibeli

Oba 1:5-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Bi awọn olè tọ̀ ọ wá, bi awọn ọlọṣà li oru, (bawo li a ti ke ọ kuro!) nwọn kì yio ha jale titi nwọn fi ni to? bi awọn aka-eso-ajara wá sọdọ rẹ, nwọn kì yio ha fi ẽṣẹ́ diẹ silẹ?

6. Bawo li a ti ṣawari awọn nkan Esau! bawo li a ti wá awọn ohun ikọkọ rẹ̀ jade!

7. Gbogbo awọn ẹni imulẹ rẹ ti mu ọ de opin ilẹ rẹ: awọn ti nwọn ti wà li alafia pẹlu rẹ ti tàn ọ jẹ, nwọn si bori rẹ; awọn ti o jẹ onjẹ rẹ ti fi ọgbẹ́ si abẹ rẹ: oye kò si ninu rẹ̀.

8. Oluwa wipe, li ọjọ na ki emi o run awọn ọlọgbọn kuro ni Edomu, ati imoye kuro li oke Esau?

9. Awọn alagbara rẹ yio si bẹ̀ru, iwọ Temani, nitori ki a le ke olukuluku ti ori oke Esau kuro nitori ipania.

10. Nitori ìwa-ipa si Jakobu arakunrin rẹ itiju yio bò ọ, a o si ke ọ kuro titi lai.

11. Ni ọjọ ti iwọ duro li apa keji, ni ọjọ ti awọn alejo kó awọn ogun rẹ̀ ni igbèkun lọ, ti awọn ajeji si wọ inu ibode rẹ̀, ti nwọn si ṣẹ keké lori Jerusalemu, ani iwọ wà bi ọkan ninu wọn.