Yorùbá Bibeli

O. Daf 92:12-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Olododo yio gbà bi igi ọpẹ: yio dàgba bi igi kedari Lebanoni.

13. Awọn ẹniti a gbin ni ile Oluwa, yio gbà ni agbala Ọlọrun wa.

14. Nwọn o ma so eso sibẹ ninu ogbó wọn: nwọn o sanra, nwọn o ma tutù nini;

15. Lati fi hàn pe, Ẹni diduro-ṣinṣin ni Oluwa: on li apata mi, kò si si aiṣododo kan ninu rẹ̀.