Yorùbá Bibeli

O. Daf 92:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OHUN rere ni lati ma fi ọpẹ fun Oluwa, ati lati ma kọrin si orukọ rẹ, Ọga-ogo:

2. Lati ma fi iṣeun ifẹ rẹ hàn li owurọ, ati otitọ rẹ li alalẹ.

3. Lara ohun-elo orin olokùn mẹwa, ati lara ohun-elo orin mimọ́: lara duru pẹlu iró ti o ni ironu.

4. Nitori iwọ, Oluwa, li o ti mu mi yọ̀ nipa iṣẹ rẹ: emi o ma kọrin iyìn nitori iṣẹ ọwọ rẹ.

5. Oluwa, iṣẹ rẹ ti tobi to! ìro-inu rẹ jinlẹ gidigidi.

6. Ope enia kò mọ̀; bẹ̃li oye eyi kò ye aṣiwere enia.

7. Nigbati awọn enia buburu ba rú bi koriko, ati igbati gbogbo awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ ba ngberú: ki nwọn ki o le run lailai ni: