Yorùbá Bibeli

O. Daf 90:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA, iwọ li o ti nṣe ibujoko wa lati irandiran.

2. Ki a to bí awọn òke nla, ati ki iwọ ki o to dá ilẹ on aiye, ani lati aiye-raiye, iwọ li Ọlọrun.

3. Iwọ sọ enia di ibajẹ; iwọ si wipe, Ẹ pada wá, ẹnyin ọmọ enia.

4. Nitoripe igbati ẹgbẹrun ọdun ba kọja li oju rẹ, bi aná li o ri, ati bi igba iṣọ́ kan li oru.

5. Iwọ kó wọn lọ bi ẹnipe ni ṣiṣan-omi; nwọn dabi orun; ni kutukutu nwọn dabi koriko ti o dagba soke.

6. Ni Kutukutu o li àwọ lara, o si dàgba soke, li asalẹ a ké e lulẹ, o si rọ.

7. Nitori awa di egbé nipa ibinu rẹ, ati nipa ibinu rẹ ara kò rọ̀ wa.

8. Iwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ wa ka iwaju rẹ, ohun ìkọkọ wa mbẹ ninu imọlẹ iwaju rẹ.