Yorùbá Bibeli

O. Daf 9:10-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Awọn ti o si mọ̀ orukọ rẹ o gbẹkẹ le ọ: nitori iwọ, Oluwa, kò ti ikọ̀ awọn ti nṣe afẹri rẹ silẹ.

11. Ẹ kọrin iyìn si Oluwa, ti o joko ni Sioni: ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia.

12. Nigbati o wadi ẹjọ-ẹ̀jẹ, o ranti wọn: on kò si gbagbe ẹkún awọn olupọnju.

13. Ṣãnu fun mi, Oluwa; rò iṣẹ́ ti emi nṣẹ́ lọwọ awọn ti o korira mi, iwọ ti o gbé ori mi soke kuro li ẹnu-ọ̀na ikú.

14. Ki emi ki o le ma fi gbogbo iyìn rẹ hàn li ẹnu-ọ̀na ọmọbinrin Sioni, emi o ma yọ̀ ni igbala rẹ.

15. Awọn orilẹ-ède jìn sinu ọ̀fin ti nwọn wà: ninu àwọn ti nwọn dẹ silẹ li ẹsẹ ara wọn kọ́.

16. A mọ̀ Oluwa, nipa idajọ ti o nṣe: nipa iṣẹ ọwọ enia buburu li a fi ndẹkùn mu u.

17. Ori awọn enia buburu li a o dà si ọrun apadi, ati gbogbo orilẹ-ède ti o gbagbe Ọlọrun.

18. Nitori pe a kì yio gbagbe awọn alaini lailai: abá awọn talaka kì yio ṣegbe lailai.