Yorùbá Bibeli

O. Daf 88:9-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Oju mi nkãnu nitori ipọnju: Oluwa, emi ti npè ọ lojojumọ, emi si ti nawọ mi si ọ.

10. Iwọ o fi iṣẹ iyanu rẹ hàn fun okú bi? awọn okú yio ha dide ki nwọn si ma yìn ọ bi?

11. A o ha fi iṣeun ifẹ rẹ hàn ni isà-òkú bi? tabi otitọ rẹ ninu iparun?

12. A ha le mọ̀ iṣẹ iyanu rẹ li okunkun bi? ati ododo rẹ ni ilẹ igbagbe?

13. Ṣugbọn iwọ ni mo kigbe si, Oluwa; ati ni kutukutu owurọ li adura mi yio ṣaju rẹ.

14. Oluwa, ẽṣe ti iwọ fi ṣa ọkàn mi tì? ẽṣe ti iwọ fi pa oju rẹ mọ́ kuro lọdọ mi?

15. Iṣẹ́ nṣẹ mi, emi mura ati kú lati igba ewe mi wá: nigbati ẹ̀ru rẹ ba mbà mi, emi di gbéregbère.

16. Ifẹju ibinu rẹ kọja lara mi; ìbẹru rẹ ti ke mi kuro.

17. Nwọn wá yi mi ka li ọjọ gbogbo bi omi: nwọn yi mi kakiri tan.

18. Olufẹ ati ọrẹ ni iwọ mu jina si mi, ati awọn ojulumọ mi ninu okunkun.