Yorùbá Bibeli

O. Daf 88:13-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ṣugbọn iwọ ni mo kigbe si, Oluwa; ati ni kutukutu owurọ li adura mi yio ṣaju rẹ.

14. Oluwa, ẽṣe ti iwọ fi ṣa ọkàn mi tì? ẽṣe ti iwọ fi pa oju rẹ mọ́ kuro lọdọ mi?

15. Iṣẹ́ nṣẹ mi, emi mura ati kú lati igba ewe mi wá: nigbati ẹ̀ru rẹ ba mbà mi, emi di gbéregbère.

16. Ifẹju ibinu rẹ kọja lara mi; ìbẹru rẹ ti ke mi kuro.

17. Nwọn wá yi mi ka li ọjọ gbogbo bi omi: nwọn yi mi kakiri tan.

18. Olufẹ ati ọrẹ ni iwọ mu jina si mi, ati awọn ojulumọ mi ninu okunkun.