Yorùbá Bibeli

O. Daf 79:7-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nitori ti nwọn ti mu Jakobu jẹ, nwọn si sọ ibujoko rẹ̀ di ahoro.

8. Máṣe ranti ẹ̀ṣẹ awọn aṣaju wa si wa: jẹ ki iyọnu rẹ ki o ṣaju wa nisisiyi: nitori ti a rẹ̀ wa silẹ gidigidi.

9. Ràn wa lọwọ, Ọlọrun igbala wa, nitori ogo orukọ rẹ: ki o si gbà wa, ki o si wẹ̀ ẹ̀ṣẹ wa nù, nitori orukọ rẹ.

10. Nitori kili awọn keferi yio ṣe wipe, Nibo li Ọlọrun wọn wà? jẹ ki a mọ̀ igbẹsan ẹ̀jẹ awọn iranṣẹ rẹ ti a ta silẹ loju wa ninu awọn keferi.

11. Jẹ ki imi-ẹdun onde nì ki o wá siwaju rẹ: gẹgẹ bi titobi agbara rẹ, iwọ dá awọn ti a yàn si pipa silẹ:

12. Ki o si san ẹ̀gan wọn nigba meje fun awọn aladugbo wa li aiya wọn, nipa eyiti nwọn ngàn ọ, Oluwa.