Yorùbá Bibeli

O. Daf 76:6-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Nipa ibawi rẹ, Ọlọrun Jakobu, ati kẹkẹ́-ogun ati ẹṣin sun orun asunkú.

7. Iwọ, ani iwọ li o ni ìbẹru: ati tani yio le duro niwaju rẹ, nigbati iwọ ba binu lẹ̃kan?

8. Iwọ mu idajọ di gbigbọ́ lati ọrun wá: ilẹ aiye bẹ̀ru o si duro jẹ.

9. Nigbati Ọlọrun dide si idajọ, lati gbà gbogbo ọlọkan-tutu aiye là.

10. Nitõtọ ibinu enia yio yìn ọ: nigbati iwọ ba fi ibinu iyokù di ara rẹ li amure.

11. Ẹ ṣe ileri ifẹ, ki ẹ si san a fun Oluwa, Ọlọrun nyin: jẹ ki gbogbo awọn ti o yi i ka ki o mu ẹ̀bun wá fun ẹniti a ba ma bẹ̀ru.

12. On o ke ẹmi awọn ọmọ alade kuro: on si di ẹ̀ru si awọn ọba aiye.