7. Nwọn tinabọ ibi-mimọ́ rẹ, ni wiwo ibujoko orukọ rẹ lulẹ, nwọn sọ ọ di ẽri.
8. Nwọn wi li ọkàn wọn pe, Ẹ jẹ ki a run wọn pọ̀: nwọn ti kun gbogbo ile Ọlọrun ni ilẹ na.
9. Awa kò ri àmi wa: kò si woli kan mọ́: bẹ̃ni kò si ẹnikan ninu wa ti o mọ̀ bi yio ti pẹ to.
10. Ọlọrun, ọta yio ti kẹgan pẹ to? ki ọta ki o ha ma sọ̀rọ òdi si orukọ rẹ lailai?
11. Ẽṣe ti iwọ fi fa ọwọ rẹ sẹhin, ani ọwọ ọtún rẹ? fà a yọ jade kuro li õkan aiya rẹ ki o si pa a run.
12. Nitori Ọlọrun li Ọba mi li atijọ wá, ti nṣiṣẹ igbala lãrin aiye.
13. Iwọ li o ti yà okun ni meji nipa agbara rẹ: iwọ ti fọ́ ori awọn erinmi ninu omi.
14. Iwọ fọ́ ori Lefiatani tũtu, o si fi i ṣe onjẹ fun awọn ti ngbe inu ijù.
15. Iwọ là orisun ati iṣan-omi: iwọ gbẹ awọn odò nla.
16. Tirẹ li ọsán, tirẹ li oru pẹlu: iwọ li o ti pèse imọlẹ ati õrun.