Yorùbá Bibeli

O. Daf 74:13-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Iwọ li o ti yà okun ni meji nipa agbara rẹ: iwọ ti fọ́ ori awọn erinmi ninu omi.

14. Iwọ fọ́ ori Lefiatani tũtu, o si fi i ṣe onjẹ fun awọn ti ngbe inu ijù.

15. Iwọ là orisun ati iṣan-omi: iwọ gbẹ awọn odò nla.

16. Tirẹ li ọsán, tirẹ li oru pẹlu: iwọ li o ti pèse imọlẹ ati õrun.

17. Iwọ li o ti pàla eti aiye: iwọ li o ṣe igba ẹ̀run ati igba otutu.

18. Ranti eyi, Oluwa, pe ọta nkẹgàn, ati pe awọn enia buburu nsọ̀rọ odi si orukọ rẹ.

19. Máṣe fi ọkàn àdaba rẹ le ẹranko igbẹ lọwọ: máṣe gbagbe ijọ awọn talaka rẹ lailai.

20. Juba majẹmu nì: nitori ibi òkunkun aiye wọnni o kún fun ibugbe ìka.

21. Máṣe jẹ ki ẹniti a ni lara ki o pada ni ìtiju; jẹ ki talaka ati alaini ki o yìn orukọ rẹ.

22. Ọlọrun, dide, gbà ẹjọ ara rẹ rò: ranti bi aṣiwere enia ti ngàn ọ lojojumọ.

23. Máṣe gbagbe ohùn awọn ọta rẹ: irọkẹ̀kẹ awọn ti o dide si ọ npọ̀ si i nigbagbogbo.