Yorùbá Bibeli

O. Daf 71:1-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA, iwọ ni mo gbẹkẹ mi le: lai máṣe jẹ ki a dãmu mi.

2. Gbà mi nipa ododo rẹ, ki o si mu mi yọ̀: dẹ eti rẹ si mi, ki o si gbà mi.

3. Iwọ ni ki o ṣe ibujoko apata mi, nibiti emi o gbe ma rè nigbagbogbo: iwọ ti paṣẹ lati gbà mi; nitori iwọ li apata ati odi agbara mi.

4. Gbà mi, Ọlọrun mi, li ọwọ awọn enia buburu, li ọwọ alaiṣododo ati ìka ọkunrin.

5. Nitori iwọ ni ireti mi, Oluwa Ọlọrun; iwọ ni igbẹkẹle mi lati igba ewe mi.

6. Ọwọ rẹ li a ti fi gbé mi duro lati inu wá: iwọ li ẹniti o mu mi jade lati inu iya mi wá: nipasẹ rẹ ni iyìn mi wà nigbagbogbo.

7. Emi dabi ẹni-iyanu fun ọ̀pọlọpọ enia, ṣugbọn iwọ li àbo mi ti o lagbara.

8. Jẹ ki ẹnu mi ki o kún fun iyìn rẹ ati fun ọlá rẹ li ọjọ gbogbo.

9. Máṣe ṣa mi ti ni ìgba ogbó; máṣe kọ̀ mi silẹ nigbati agbara mi ba yẹ̀.

10. Nitori awọn ọta mi nsọ̀rọ si mi; awọn ti nṣọ ọkàn mi si gbimọ̀ pọ̀.

11. Nwọn wipe, Ọlọrun ti kọ̀ ọ silẹ: ẹ lepa ki ẹ si mu u; nitori ti kò si ẹniti yio gbà a.

12. Ọlọrun, máṣe jina si mi: Ọlọrun mi, yara si iranlọwọ mi.

13. Jẹ ki nwọn ki o dãmu, ki a si run awọn ti nṣe ọta ọkàn mi, ki a si fi ẹ̀gan ati àbuku bo awọn ti nwá ifarapa mi.

14. Ṣugbọn emi o ma reti nigbagbogbo, emi o si ma fi iyìn kún iyìn rẹ.

15. Ẹnu mi yio ma fi ododo rẹ ati igbala rẹ hàn li ọjọ gbogbo; emi kò sa mọ̀ iye rẹ̀.

16. Emi o wá li agbara Oluwa Ọlọrun; emi o ma da ọ̀rọ ododo rẹ sọ, ani tirẹ nikan.