Yorùbá Bibeli

O. Daf 68:8-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ilẹ mì, ọrun bọ silẹ niwaju Ọlọrun: ani Sinai tikararẹ̀ mì niwaju Ọlọrun, Ọlọrun Israeli.

9. Ọlọrun, iwọ li o rán ọ̀pọlọpọ òjo si ilẹ-ini rẹ, nigbati o rẹ̀ ẹ tan, iwọ tù u lara.

10. Ijọ enia rẹ li o tẹ̀do sinu rẹ̀: iwọ Ọlọrun ninu ore rẹ li o ti pèse fun awọn talaka.

11. Oluwa ti sọ̀rọ: ọ̀pọlọpọ si li ogun awọn ẹniti nfi ayọ̀ rohin rẹ̀:

12. Awọn ọba awọn ẹgbẹ ogun sa, nwọn sa lọ: obinrin ti o si joko ni ile ni npin ikogun na.

13. Nigbati ẹnyin dubulẹ larin agbo ẹran, nigbana ni ẹnyin o dabi iyẹ adaba ti a bò ni fadaka, ati ìyẹ́ rẹ̀ pẹlu wura pupa.