Yorùbá Bibeli

O. Daf 64:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌLỌRUN, gbohùn mi ninu aroye mi: pa ẹmi mi mọ́ lọwọ ẹ̀ru ọta nì.

2. Pa mi mọ́ lọwọ ìmọ ìkọkọ awọn enia buburu: lọwọ irukerudo awọn oniṣẹ-ẹ̀ṣẹ.

3. Ẹniti npọ̀n ahọn wọn bi ẹnipe idà, ti nwọn si fa ọrun wọn le lati tafa wọn, ani ọ̀rọ kikoro:

4. Ki nwọn ki o le ma tafà ni ìkọkọ si awọn ti o pé: lojiji ni nwọn tafa si i, nwọn kò si bẹ̀ru.

5. Nwọn gba ara wọn niyanju li ọ̀ran buburu: nwọn gbìmọ ati dẹkun silẹ nikọ̀kọ; nwọn wipe, Tani yio ri wọn?

6. Nwọn gbero ẹ̀ṣẹ; nwọn wipe, awa ti pari ero ti a gbà tan: ati ìro inu olukuluku wọn, ati aiya wọn, o jinlẹ.

7. Ṣugbọn Ọlọrun yio tafà si wọn lojiji; nwọn o si gbọgbẹ.