1. ỌLỌRUN mi, gbà mi lọwọ awọn ọta mi: dãbobo mi lọwọ awọn ti o dide si mi.
2. Gbà mi lọwọ awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ, ki o si gbà mi silẹ lọwọ awọn enia-ẹ̀jẹ.
3. Sa kiyesi i, nwọn ba ni buba fun ọkàn mi, awọn alagbara pejọ si mi; kì iṣe nitori irekọja mi, tabi nitori ẹ̀ṣẹ mi, Oluwa.
4. Nwọn sure, nwọn mura li aiṣẹ mi: dide lati pade mi, ki o si kiyesi i.
5. Nitorina iwọ, Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, jí lati bẹ̀ gbogbo awọn keferi wò; máṣe ṣãnu fun olurekọja buburu wọnni.
6. Nwọn pada li aṣalẹ: nwọn npariwo bi ajá, nwọn nrìn yi ilu na ka.
7. Kiyesi i, nwọn nfi ẹnu wọn gùfẹ jade: idà wà li ète wọn: nitoriti nwọn nwipe, tali o gbọ́?
8. Ṣugbọn iwọ, Oluwa, yio rẹrin wọn: iwọ ni yio yọṣuti si gbogbo awọn keferi.
9. Agbara rẹ̀ li emi o duro tì: nitori Ọlọrun li àbo mi.
10. Ọlọrun ãnu mi ni yio ṣaju mi: Ọlọrun yio jẹ ki emi ri ifẹ mi lara awọn ọta mi.
11. Máṣe pa wọn, ki awọn enia mi ki o má ba gbagbe: tú wọn ká nipa agbara rẹ; ki o si sọ̀ wọn kalẹ, Oluwa asà wa.
12. Nitori ẹ̀ṣẹ ẹnu wọn ni ọ̀rọ ète wọn, ki a mu wọn ninu igberaga wọn: ati nitori ẽbu ati èke ti nwọn nṣe.