Yorùbá Bibeli

O. Daf 57:5-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Gbigbega ni ọ, Ọlọrun, jù ọrun lọ; ati ogo rẹ jù gbogbo aiye lọ.

6. Nwọn ti ta àwọn silẹ fun ẹsẹ mi: nwọn tẹ ori ọkàn mi ba: nwọn ti wà iho silẹ niwaju mi, li ãrin eyina li awọn tikarawọn jìn si.

7. Ọkàn mi ti mura, Ọlọrun, ọkàn mi ti mura: emi o kọrin, emi o si ma kọrin iyìn.

8. Jí, iwọ ogo mi; jí, ohun-èlo orin ati duru: emi tikarami yio si jí ni kutukutu.

9. Emi o ma yìn ọ, Oluwa lãrin awọn enia: emi o si ma kọrin si ọ lãrin awọn orilẹ-ède.

10. Nitoriti ãnu rẹ pọ̀ de ọrun, ati otitọ rẹ de awọsanma.

11. Gbigbega ni ọ, Ọlọrun, jù awọn ọrun lọ ati ogo rẹ jù gbogbo aiye lọ.