1. ẸGBỌ́ eyi, gbogbo enia; ẹ fi eti si i, gbogbo ẹnyin araiye:
2. Ati awọn ọmọ-ẹhin ati awọn ẹni-ọlá, awọn ọlọrọ̀ ati awọn talaka pẹlu.
3. Ẹnu mi yio sọ̀rọ ọgbọ́n, ati iṣaro aiya mi yio jẹ oye.
4. Emi o dẹ eti mi silẹ si owe: emi o ṣi ọ̀rọ ìkọkọ mi silẹ loju okùn dùru.
5. Ẽṣe ti emi o fi bẹ̀ru li ọjọ ibi, nigbati ẹ̀ṣẹ awọn ajinilẹsẹ mi yi mi ka.
6. Awọn ti o gbẹkẹle ọrọ̀ wọn, ti nwọn si nṣe ileri li ọ̀pọlọpọ ọrọ̀ wọn;
7. Kò si ẹnikan, bi o ti wù ki o ṣe, ti o le rà arakunrin rẹ̀, bẹ̃ni kò le san owo-irapada fun Ọlọrun nitori rẹ̀.
8. Nitori irapada ọkàn wọn iyebiye ni, o si dẹkun lailai:
9. Nipe ki o fi mã wà lailai, ki o má ṣe ri isa-okú.