Yorùbá Bibeli

O. Daf 46:5-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Ọlọrun mbẹ li arin rẹ̀; a kì yio ṣi i ni idi: Ọlọrun yio ràn a lọwọ ni kutukutu owurọ.

6. Awọn keferi nbinu, awọn ilẹ ọba ṣidi: o fọhun rẹ̀, aiye yọ́.

7. Oluwa awọn ọmọ-ogun wà pẹlu wa; Ọlọrun Jakobu li àbo wa.

8. Ẹ wá wò awọn iṣẹ Oluwa, iru ahoro ti o ṣe ni aiye.

9. O mu ọ̀tẹ tan de opin aiye; o ṣẹ́ ọrun, o si ke ọ̀kọ meji; o si fi kẹkẹ́ ogun jona.

10. Ẹ duro jẹ, ki ẹ si mọ̀ pe emi li Ọlọrun, a o gbé mi ga ninu awọn keferi, a o gbé mi ga li aiye.

11. Oluwa awọn ọmọ-ogun wà pẹlu wa; Ọlọrun Jakobu li àbo wa.