Yorùbá Bibeli

O. Daf 44:15-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Idamu mi mbẹ niwaju mi nigbagbogbo, itiju mi si bò mi mọlẹ.

16. Nitori ohùn ẹniti ngàn, ti o si nsọ̀rọ buburu; nitori ipa ti ọta olugbẹsan nì.

17. Gbogbo wọnyi li o de si wa; ṣugbọn awa kò gbagbe rẹ, bẹ̃li awa kò ṣe eke si majẹmu rẹ.

18. Aiya wa kò pada sẹhin, bẹ̃ni ìrin wa kò yà kuro ni ipa tirẹ;

19. Bi iwọ tilẹ ti fọ́ wa bajẹ ni ibi awọn ikõkò, ti iwọ si fi ojiji ikú bò wa mọlẹ.

20. Bi o ba ṣepe awa gbagbe orukọ Ọlọrun wa, tabi bi awa ba nà ọwọ wa si ọlọrun ajeji;

21. Njẹ Ọlọrun ki yio ri idi rẹ̀? nitori o mọ̀ ohun ìkọkọ aiya.

22. Nitõtọ, nitori rẹ li a ṣe npa wa kú ni gbogbo ọjọ; a nkà wa si bi agutan fun pipa.

23. Ji! ẽṣe ti iwọ nsùn, Oluwa? dide, máṣe ṣa wa tì kuro lailai.

24. Ẽṣe ti iwọ fi pa oju rẹ mọ́, ti iwọ si fi gbagbe ipọnju wa ati inira wa?

25. Nitoriti a tẹri ọkàn wa ba sinu ekuru: inu wa dì mọ erupẹ ilẹ.

26. Dide fun iranlọwọ wa, ki o si rà wa pada nitori ãnu rẹ.