Yorùbá Bibeli

O. Daf 44:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌLỌRUN, awa ti fi eti wa gbọ́, awọn baba wa si ti sọ fun wa ni iṣẹ́ nla ti iwọ ṣe li ọjọ wọn, ni igbà àtijọ́.

2. Bi iwọ ti fi ọwọ rẹ lé awọn keferi jade, ti iwọ si gbin wọn: bi iwọ ti fõró awọn enia na, ti iwọ si mu wọn gbilẹ.

3. Nitoriti nwọn kò ni ilẹ na nipa idà ara wọn, bẹ̃ni kì iṣe apá wọn li o gbà wọn; bikoṣe ọwọ ọtún rẹ ati apá rẹ, ati imọlẹ oju rẹ, nitoriti iwọ ni ifẹ rere si wọn.

4. Iwọ li Ọba mi, Ọlọrun: paṣẹ igbala fun Jakobu.

5. Nipasẹ̀ rẹ li awa o bì awọn ọta wa ṣubu: nipasẹ orukọ rẹ li awa o tẹ̀ awọn ti o dide si wa mọlẹ.

6. Nitoriti emi kì yio gbẹkẹle ọrun mi, bẹ̃ni idà mi kì yio gbà mi.

7. Ṣugbọn iwọ li o ti gbà wa lọwọ awọn ọta wa, iwọ si ti dojutì awọn ti o korira wa.

8. Niti Ọlọrun li awa nkọrin iyìn li ọjọ gbogbo, awa si nyìn orukọ rẹ lailai.

9. Ṣugbọn iwọ ti ṣa wa tì, iwọ si ti dojutì wa: iwọ kò si ba ogun wa jade lọ.

10. Iwọ mu wa pẹhinda fun ọta wa: ati awọn ti o korira wa nṣe ikogun fun ara wọn.

11. Iwọ ti fi wa fun jijẹ bi ẹran agutan; iwọ si ti tú wa ka ninu awọn keferi.

12. Iwọ ti tà awọn enia rẹ li asan, iwọ kò si fi iye-owo wọn sọ ọrọ̀ rẹ di pupọ.