Yorùbá Bibeli

O. Daf 36:4-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. O ngbèro ìwa-ika lori ẹni rẹ̀: o gba ọ̀na ti kò dara; on kò korira ibi.

5. Oluwa, ãnu rẹ de ọrun; otitọ rẹ de awọsanma.

6. Ododo rẹ dabi awọn òke Ọlọrun; idajọ rẹ dabi ibu nla: Oluwa, iwọ pa enia ati ẹranko mọ́.

7. Ọlọrun, iṣeun-ifẹ rẹ ti dara to! nitori na li awọn ọmọ enia yio ma gbẹkẹ wọn le abẹ ojiji iyẹ-apa rẹ.

8. Ororo ile rẹ yio tẹ wọn lọrùn gidigidi; iwọ o si mu wọn mumi ninu odò ifẹ rẹ.

9. Nitori pe pẹlu rẹ li orisun ìye wà: ninu imọlẹ rẹ li awa o ma ri imọlẹ.

10. Mu iṣeun ifẹ rẹ pẹ si awọn ti o mọ̀ ọ; ati ododo rẹ fun awọn alaiyà diduro.

11. Máṣe jẹ ki ẹsẹ agberaga ki o wá si mi, ki o má si jẹ ki ọwọ enia buburu ki o ṣi mi ni ipò.

12. Nibẹ li awọn oniṣẹ-ẹ̀ṣẹ gbe ṣubu: a rẹ̀ wọn silẹ, nwọn kì yio si le dide.