Yorùbá Bibeli

O. Daf 35:13-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, nigbati ara wọn kò dá, aṣọ àwẹ li aṣọ mi: mo fi àwẹ rẹ̀ ọkàn mi silẹ; adura mi si pada si mi li aiya.

14. Emi ṣe ara mi bi ẹnipe ọrẹ tabi arakunrin mi tilẹ ni: emi fi ibinujẹ tẹriba, bi ẹniti nṣọ̀fọ iya rẹ̀.

15. Ṣugbọn ninu ipọnju mi nwọn yọ̀, nwọn si kó ara wọn jọ: awọn enia-kenia kó ara wọn jọ si mi, emi kò si mọ̀; nwọn fa mi ya, nwọn kò si dakẹ.

16. Pẹlu awọn àgabagebe ti iṣe ẹlẹya li apejẹ, nwọn npa ehin wọn si mi.

17. Oluwa iwọ o ti ma wò pẹ to? yọ ọkàn mi kuro ninu iparun wọn, ẹni mi kanna lọwọ awọn kiniun.

18. Emi o ṣọpẹ fun ọ ninu ajọ nla: emi o ma yìn ọ li awujọ ọ̀pọ enia.

19. Máṣe jẹ ki awọn ti nṣe ọta mi lodi ki o yọ̀ mi; bẹ̃ni ki o má si ṣe jẹ ki awọn ti o korira mi li ainidi ki o ma ṣẹju si mi.

20. Nitori ti nwọn kò sọ̀rọ alafia: ṣugbọn nwọn humọ ọ̀ran ẹ̀tan si awọn enia jẹjẹ ilẹ na.

21. Nitotọ, nwọn ya ẹnu wọn silẹ si mi, nwọn wipe, A! ã! oju wa ti ri i!

22. Eyi ni iwọ ti ri, Oluwa: máṣe dakẹ: Oluwa máṣe jina si mi.

23. Rú ara rẹ soke, ki o si ji si idajọ mi, ati si ọ̀ran mi, Ọlọrun mi ati Oluwa mi.

24. Ṣe idajọ mi, Oluwa Ọlọrun mi, gẹgẹ bi ododo rẹ, ki o má si ṣe jẹ ki nwọn ki o yọ̀ mi.

25. Máṣe jẹ ki nwọn kí o wi ninu ọkàn wọn pe, A! bẹ̃li awa nfẹ ẹ: máṣe jẹ ki nwọn ki o wipe, Awa ti gbé e mì.

26. Ki oju ki o tì wọn, ki nwọn ki o si dãmu pọ̀, ti nyọ̀ si ifarapa mi: ki a fi itiju ati àbuku wọ̀ wọn ni aṣọ, ti ngberaga si mi.

27. Jẹ ki nwọn ki o ma hó fun ayọ̀, ki nwọn ki o si ma ṣe inu-didùn, ti nṣe oju-rere si ododo mi: lõtọ ki nwọn ki o ma wi titi pe, Oluwa ni ki a ma gbega, ti o ni inu-didùn si alafia iranṣẹ rẹ̀.

28. Ahọn mi yio si ma sọ̀rọ ododo rẹ, ati ti iyìn rẹ ni gbogbo ọjọ.